01/07/2026
Ọdún ọmọ Ejio, Ayọ̀ ọmọ Ọbàlọràn, Àkànnàmọ̀gbò kìí pọdún jẹ,
Emi Ọlálékan aa pẹ́ láyé bí ewé àpẹ́, Pípẹ́ ni ti pẹ́pẹ́ nígbó, Pípẹ́ ni bàtà ń pẹ́ lẹ́sẹ̀ pẹ́pẹ́yẹ, Kánrinkéṣe ni Èṣù ń pẹ́ lójú òde,
Ọ̀pọ́n kò ní sé kankan
Òkùtẹ̀ kò ní yẹ̀ bọ̀rọ̀bọ̀rọ̀
Omi agbada kò ní dànù wàràwàrà
Asodun modun niisawo a*odun modun,
Asosu mosu níí ṣawo a*osu mosu,
Ọdọọdún láárí orógbó
Ọdọọdún láárí awùsá,
Ọdọọdún láárí ọmọ obi lórí àtẹ
Ọdọọdún ni s'apo nruwe
Ọdọọdún ni peregun ni láṣọ ma*o
Igúnnugún kii kuu l'ewe ma kasai d'arugbo
Akalamagbo kii podun jẹ mio nii pàá odun jẹ
ponri ponri ni fi enu ara re sako, Ogbologbo akuroo ni ko ara re lebe, Gbiirigbiri daji daji gbirigbiri, aja bawon lo ree ba won bọ orun oyinbo, aja de orun oyinbo, oni ohun mo gbogbo yin gbogbo gbooo, won ni nigbati o sope o mo gbogbo awon gbogbo gboo, won ni talo mo, oni ohun mo oba pata pata tin ba won da buro oje, oni ohun mo oba pata pata tin ba won da jii koo, oni ohun mo alawo sarasara tin ba won da osu, oni ohun mo laluba, oni ohun mo orinrin monle, oni ohun mo eleiye lowe, oni ohun mo ona gbooro tife wa, won nigbati o sope o mo gbogbo awon gbogbo gboo, Tani o mo, oni ohun mo oba pata pata tin bawon da buro ojee, won ni tani oba pata pata tin bawon da buro ojee?, oni oba pata pata tin ba won da buro oje loruko tia npe orisa nla, orisa nla ni haa o mo oruko ohun, oni omi ara ohun tohun lo nse, oni eje ara ohun tohun lo nse, oni omo ara ohun tohun lo nse emi Kazeem omo Adepoju timo oruko orisa nla, oni omi tio wa lara mi koma baje, eje tio wa lara mi kio ma baje.
Ni aja ba tun lo, won ni kio pada kio ma tii lo, won ni nigbati o mo gbogbo awon gbogbo gboo, Tani o tun mo, oni ohun mo oba pata pata tin ba won da jii koo, won ni tani oba pata pata tin bawon da jii koo?, oni oba pata pata tin ba won da jii ko loruko tia npe iyemoja, iyemoja ni haa, o mo oruko ohun, yemoja ni omi inu igbo tohun ni se, yemoja ni omi inu odan tohun ni se, ti aja ba lo tio bade ibiti omi bakun omi koni gbe aja lo, aja kosi ni ri ija omi emi kazeem omo Adepoju moti mo oruko iyemoja kin ma se ri ija omi .
Ni aja ba tun lo, ni won bani ki aja ma tii lo, won bani talo tun mo, oni ohun mo alawo sarasara tin ba won da osu, won ni tani alawo sarasara tin bawon da osu?, oni alawo sarasara tin ba won da osu la npe esu odara, esu odara ni haa o mo oruko ohun, oni ohun ni ohun ma ti eniyan ni iti kuti loba iku, ohun ni ohun ma ti eniyan loba oso, loba aje, loba omo araye, nigbati o bari bee emi kazeem omo Adepoju timo oruko tia npe iwo esu odara, ki esu odara kio mase semi, eni ti esu odara ba ma se iwaju ni kio se si.
Ni aja ba tun lo, won ni ki aja ma tii lo, won tani o tun mo?, NI aja bani ohun mo laluba, won ni tani laluba,?, oni laluba ni oruko tia npe ifa, laluba ni haaa o mo oruko ohun, ifa ni alaasan ohun ni iranse re, ologede ohun ni iranse re, ifa ni alapeta ohun ni iranse re, ifa ni alasasi ohun ni iranse re, ifa ni alaburu ohun ni iranse re, etc,
Gbogbo ise buruku ti won ba ransi emi kazeem omo Adepoju ki won ma jise nitoripe moti mo oruko ifa.
Ni aja batun lo, won ni ki aja ma tii lo, won nigbati o mo gbogbo awon tan?, Won ni talo tun mo, oni ohun mo orinrinmonle, won ni tani orinrinmonle?, oni orinrinmonle loruko tanpe osun, osun ni haaa o mo oruko ohun, oni orififo ohun lo se, eyin didun ohun lo se, emi kazeem omo Adepoju timo oruko iwo osun, gbogbo inkan ti won ma nfi seni mase jeki o semi.
Ni aja ba tun lo, won ni ki aja ma tii lo, won ni nigbati o mo gbogbo awon tani o tun mo?, oni ohun mo eleiye lowe, won ni tani eleiye lowe?, eleiye lowe loruko tia npe aje, Awon aje ni haaa o mo oruko awon, won ni losan awon a mase ipade, loru awon a mase ipade, won ni enikeni tio ba bawon nibe awon yio paje ni, won nitori naa enikeni tio ba nse ipese ti aja ba jee awon ti gba niyen, nitori naa tie bati nse ipade timo bayin nibe kie mase pami je, timo ba lowo kie mase bami ja, timo ba nkole kie ma bami ja, timo ba bimo kie ma ba mija, timo ba nse ohun rere kie mase bami ja rara.
Ni aja batun lo, won ni kio pada kio ma tii lo, won ni nigbati o sope o mo gbogbo awon gbogbo gboo, Tani o tun mo?, oni ohun mo ona gbooro tife wa, won ni tani ona gbooro tife wa, oni ona gbooro tife wa loruko tia npe obo, obo ni haaa o mo oruko ohun, obo ni ti iku yio ba waye ona obo ni yio gba waye, won ni ti aje yio ba waye ona obo ni yio gba waye, won ni ti oba yio ba waye ona obo ni yio gba waye, won ni ti ijii yio ba waye ona obo ni yio gba waye, won ni ti okunrin, obinrin, omode, agbalagba yio ba waye ona obo ni gbogbo won yio gba waye, won ni tio ba ri bee pe emi Kazeem omo Adepoju timo oruko tia npe obo, gbogbo eni ti obo bati bi tio ba npe mi laida kio mase ranmi ooo, Nitoripe moti mo oruko iwo obo je, ki oso darijinmi, ki aje darijinmi, ki gbogbo eniti mo ba se kiwon o darijinmi
ORIN ::
Odundun dee omo elewu akoko ooo, odundun dee ooo omo elewu akoko ooo, odundun seni kio pero lemi lori, Ifa nise ni kio pero lemi lori, orunmila nise ni kio pero lemi lori, nitori tojo terun ile igbin kii gbe beni kii gbona, ki ile emi Kazeem omo Adepoju kio ma gbona, ki aye mi kio ma gbona lailai ! ASE !!
Oran ha! nii pa kanakana, Oran haa! mi ni koma paa alaroka, adaunse, aje, OSO, babalawo,onisegun, Alfa, wooli, okunrin, obinrin, loko lobo ti won ba nba mi soa.
Oran haa! mi ni koma paa gbogbo awon ota mi
Okere kiiji koma sunkun ninu igbo,
Ki oran ekun o ma ba gbogbo awon ota mi
Eye oori kiiji koma sunkun ninu igbo,
Ki Oran ekun o ma ba gbogbo awon ota mi Loni
Nitoripe ewe kii gbe Ori OSU kadun,
Ki gbogbo awon ota mi o ma kadun lorile aye
Olugbohungaga kii na oja abarisa dale,
Ki gbogbo awon ota mi o ma di ale Lori Ile aye
Ojo ti akerejupon ba fi enu kan Ile nii kan ilepa
Ki awon Oran ekun ma ba gbogbo awon ota mi
Toripe a*o ofo ti ogede ba daa, arare nii fi wo
Gbogbo aburu ti awon ota mi ba se simi , Ori Ara won niki won o ma fi ruu aburu won!
Ojo tomode ba dariso apa, ojo naa ni apa npa je!
Oojo ti omode ba dariso iroko, ojo naa ni iroko nkoo danu!
Ojo ti omode ba dariso oruru, ojo naa ni won NRI oku re toko wale ,
Ojo ti agbonrin ba dariso olode, Inu agbara eje nii sun !
Gbogbo igi ti OSE ba ba laye, dandan ni ki won o fi ose sile saye lo sorun alakeji
Gbogbo igi ti o ba ba OSE laye, dandan ni ki won o fi ose sile saye lo sorun aree ma bo !
Enu enu ni ese fi npa ekuro oju ona,
Ota emi Baba Ogbon awon agba international, lokunrin, lobinrin, ki won o ma fi mi sile sayo lo sorun alakeji !
HAPPY BIRTHDAY TO ME ,
BABA OGBON AWON AGBA INTERNATIONAL,
BABA ASOOREGESIN!!