30/05/2026
I use this medium to say big thanks to you all “INSU” for the honor and recognition of the award. am so grateful, wish you all more wisdom knowledge and success in your careers.
Ifa says:-
Ìríbí lawo Ìríbí
Iripon lawo iripon
Ọkan gbin-gbin-gbin awo e-ti ọsun
Adifafun orisanla ọsẹrẹmọgbo
Eyi ti mun ẹnu ẹkun sugbere ọmọ
Ẹbọ lawo ni kose, o gbe ẹbọ o rubọ
Igba ti yio bi ọmọ meje lobi,
O bi gbogbo wọn labo-labo
O mun ọmọ kan o fun Alara, Alara kọ bẹni kodupẹ,
O mun ọmọ kan o fun Ajero, Ajero kọ bẹ ni kodupẹ,
O mun ọmọ kan o fun Ọwarangun aga, Ọwarangun aga kọ bẹni kodupẹ, O fun lọja-lọja, ofun lade-lade, o fun lokọ-lokọ, gbogbo wọn kọ bẹ ni wọn ko dupẹ, o wa ku Aina ni kan nlẹ, ti nse ọmọ ikanyin wọn lenje-lenje, Awọn také-také awo ilu itake, lọfa-lọfa awo ode ilọfa, awọn igun-nu-gun nijẹ ẹbọ ti wọn ko ki ọnigba, akalamọngbo nijẹ eedi ti wọn ko ki eledi pe o ku aisun o ku aiwo, awọn ni wọn se ifa fun ọrumila ifa nlọ le fẹ Aina ti nse ọmọ orisa igbaowuji, ni igba ti o di ọjọ keji ọrunmila ransẹsi mọpẹdu awo ile alara, o ransẹ si kiyan kiyan awo oke ijero, o ransẹ si awọn yinni-yinni kẹni o semi si fun-ni, ọrunmila kun wọn wọnjẹ mẹrin, wọn kọri si ile orisa ignowuji, igba ti wọn dele orisa igba owuji, oosa ni kinlode? Wọn ni awọn wa dupẹ Aina ọmọrẹ ni, oosa ra ẹru kan silẹ ọrẹ njẹ, oni ẹni ti o ba tiwa dupẹ
Ki o mọn mun ọrẹ lọọ, njẹ modupẹ mogba ọrẹ, modupẹ Aina mo gbq ọrẹ omiran.
I use this ifa verses to show my gratitude to you all “ILOBU NATIONAL STUDENT UNION” once again i really appreciate you all.