31/07/2026
♌LEO (JULY 23 - AUG 22): ÌRAWỌ ỌLỌLA ATÍ ONÍPO♌
👉Awọn ọmọ onirawọ ina togbonariri jẹ ẹ̀dá eniyan ti Ọlọrun da ọla mọ lọpọlọpọ lati ode ọrun, ọla wọn a ma mọlẹ a si ma tan bí ti oorun latara irawọ adayeba eyi ti a fi ṣẹda wọn sinu aye. Wọn jẹ ẹ̀dá eniyan ti o saba ma n di ipo alagbara ati ipo pataki mu ninu aye bii ipo Arẹ orílẹ-ede, Gomina ipinlẹ ede, Alaga ijọba ibilẹ, Ọga awọn ọmọṣẹ ologun bi army, soldier, agbonfinro ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ọwọ wọn ma n ji si owo lati kekere bẹẹ wọn ma n saba tete di ẹni nla wọn si ma n tete de ipo agbara, aṣẹ tàbí ipele giga ninu aye papa julọ eyi ti o ba tete ṣe awari ara rẹ lasiko.
👉Alagbara ati akinkanju eniyan ti kí bẹru ohunkohun ni wọn jẹ bẹẹ iwa ìdánilójú ati nini igbagbọ ninu ara ẹni eyi ti Ọlọrun da mọ wọn lati ode ọrun ma n jẹ ki wọn ni igbagbọ wipe ko si ohunkohun ti wọn ba na ọwọ si ti ko ni ṣalai jẹ ti wọn. Awọn ọmọ onirawọ iná togbonariri ko ṣe ba fi ori gbari nitori ọba ní wọn láàrin àwùjọ awa eniyan latara ẹya kiniun eyi ti wọn jẹ. Ti wọn ba n rin jinijini a ma bolẹ, ti wọn ba n sọrọ ẹru a ma ba awọn eniyan, tí wọn ba yọ sibi kan tàbí halẹ awọn eniyan a si ma paramọ ki ṣe agbara awọn na bikoṣe adamọ wọn lati ode ọrun.
👉Ori ade, ori oye, ori ọla ati ori ipo ni ori awọn ọmọ onirawọ yi láti ode ọrun nitori wipe aṣáájú, oludari ati olùṣàkóso ni Ẹlẹda fi wọn ṣe sinu aye. Ko si ipo alagbara, ipo aṣẹ tabi ipo ọla ti wọn ko ni ṣalaisi nibẹ ṣe láàrin awọn lọbalọba ni, láàrin awọn ijoye ilu ni, láàrin awọn ti n ṣe ìṣakoso orílẹ-ede, ipinlẹ ede ati agbaye ni, láàrin awọn oṣíṣẹ ologun ni, láàrin awọn ọlọ́lá ati ọ̀tọ̀kùlú ilu ni, láàrin awọn gbajumọ ati ìlùmọ́- ka aye ni, láàrin awọn ọga tabi oludasilẹ ile ìṣẹ ni, gbogbo rẹ pata lẹ o ti ba wọn nitori awọn gan-an ni eledumare ko ìṣakoso aye le lọwọ.
👉Adunbarin matoṣi ni awọn ọmọ onirawọ yi bẹẹ ọmọ ologo didan ni wọn. Ọpọ eniyan a ma jẹ anfani wọn latara kiko ọla ran eniyan, yàtọ̀sí eyi awọn eniyan a ma bẹru lati rẹ olólùfẹ́, ẹbi, ara, ọrẹ ati awọn eniyan wọn jẹ tabi ta abuku ba awọn eniyan wọn nitori wahala ni ti wọn ba gbọ wipe eniyan kan ṣe aida tabi ta abuku ba awọn eniyan wọn. Wọn a ma mura ko wuyi, afinju ẹ̀dá ni wọn jẹ bẹẹ gbogbo ibi tí wọn ba de awọn eniyan ma n gba ti wọn nitori wọn ni iwa ikonimọra, ọgbọn ati agbara ìṣàkóso ati adari.
👉Bi ọla awọn ọmọ onirawọ yi ṣe dun to ti wọn si jẹ alagbara ati onipo, wọn gbọdọ ma ṣọra fun iwa ibinu, igbonara, agidi, ija, adanikan-jẹ tabi imọtara-ẹni-nikan, wọn gbọdọ ma kiyesara nibi gbogbo kí wọn si ma ṣọ iwa hu nítorí ọta ati iditẹ ma n pọ fun wọn ti eyi ki jẹ ki ẹmi ọla wọn o gun tabi pẹ. Agbara, ipo ati ọla a ma gun wọn ti eyi ma n jẹ ki pupọ wọn ṣiwahu idi niyi ti wọn fi gbọdọ ma ṣe pẹlẹpẹlẹ ninu aye papa julọ eyi ti ọwọ rẹ bá ti tẹ eeku-da ti o wa ni ipo aṣẹ tabi agbara. Ọpọ eniyan ma n ṣe bi wipe wọn gba ti wọn sugbọn ifẹ oju lasan ni nitori ẹni ti o sunmọ wọn ju ni o saba ma n dalẹ wọn. Wọn gbọdọ ṣọra fun ọrẹ ati ẹgbẹ ṣíṣe gidigan.
👉Awọn obinrin onirawọ yi na jẹ arẹwa ati ẹ̀dá ti o ma n wu ọkùnrin lọpọlọpọ sugbọn wọn gbọdọ ṣọra fun iwa igbonara, owu jijẹ, ati ijẹ gaba le ọkunrin lori kí wọn sì ma kún fún ìwà ìtẹríba ati irẹlẹ ki igbeyawo wọn ba le tọjọ ki o si le so eso rere.
🌺Fun ayẹwo, iwadi àti awari lori ọrọ igbesi aye wa, láti mọ akọsẹjaye, kádàrá àti ayanmọ wa, lati mọ ìṣẹ aṣela wa, láti mọ irú ọkọ/aya ti a le fẹ, láti mọ òrìṣà idile/irawọ wa, lati mọ boya ọmọ ẹlẹgbẹ ni wa, orukọ ẹgbẹ wa, fun ẹru ẹgbẹ didi tabi ẹgbẹ bibọ, fun ìpínyà láàrin wa ati ọkọ/aya ọrun wa, fun ìṣẹ igbiyanju eyi ti o ba kadara, ayanmọ ati irawọ wa mu, fun orí bibọ, fun ibaniwaya/ọkọ, fun ala ati itumọ rẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ẹ message mi lori whatsapp: 👇👇
0904 025 5987🌺
👉N.B: Ayẹwo ki ṣe ọfẹ sugbọn owo rẹ ko gani lara.
✍PENNED BY ALPHAJOSEPH
Joseph Igbekele Ajayi
Àsiri Irawọ Gbogbo Ẹda Eniyan
ASIRI IRAWO GBOGBO EDA ENIYAN