12/05/2020
* MA SE WAYE ASAN *
Gbogbo nkan ti olohun da sinu aye daradara ni sugbon Afowofa omo eniyan loman fa wahala ati idaamu sinu aye re , kilode ti wahala Ati idaamu po pupo ninu aye lode Oni ,? Wahala owo ati Idojuko olokan ojokan awon isoro lopoju nisinyi , Sugbon Olori wahala ti a n koju nisinyi meta , meta yi na losi lagbara ju nitoripe Ona meteeta yi ni eniyan tobafe se daada maa gba koja ,
* Ibujoko
* Oogun Aye
* Jija Osi(Wiwa owo)
Mofe sowipe 67% Ni Eniyan tojewipe Won kosini Ile oko tabi tiwon koni iyawo Nile , besini Didalemosu tipoju lode Oni , Gbogbo omobirin ni won koni Ori okunrin mo besini awon okunrin na koju wahala iyawo nini, Kilofa iru wahala bayi lode Oni ? Eyin ojogbon ema bami kalo ninu oro mi nitoripe Awon ona bi meji loman fa iru wahala bee :-
√ Aise iwadi siwaju kia to ni Oko tabi ni iyawo
√ Aini itelorun ati Iteriba fun oko
Iwadi se Pataki ninu aye omo eda nitorina Ejeki a maase iwadi ohun Gbogbo siwaju igbese ,Ni aye Atijo awon Baba wa maa gbiyanju Latise iwadi siwaju nini oko tabi Aya ,
* Eleekeji Ni wipe Didojuko Isoro Awon Ota , Ranti wipe Gbogbo eniti o ba fe je Eniyan ninu aye gbodo ni Isoro besini inu ina ni wura ati fadaka la koja, masejeki Isoro bori re , gbiyanju lati bori Isoro , sunmo awon onimimo kí wọn fi ona mon. latimo nkan ti eleda re n fe ati nkan ti kofe,
*Eleketa ni jija Ogun osi , eniyan gbodo jagun osi kuro ninu aye re nitoripe Olohun koda enikookan wasile aye lasan lainidi kan pato besini igbiyanju die ni Elomiran n fe ninu aye re sugbon ailejade ati jijoko tetere lose okunfa osi ati Wahala sinu aye re. Ma se waye Asan, Ma se joko sojukan na , Ise onise ni Elomiran n se , Aya alaya ni Elomiran fe sile , gbiyanju latimo iru irawo re pelu ohun toromo irawo re