25/12/2025
Ifa mo júbà
EJIOGBE 7
Ifa wipe
Ejeji ni mo gbe
Nko gbe ẹni kan
Ti Aye ba yẹ ni layẹju
Ọba ni wọn nfi ni jẹ
Gbọgbọgbọ lọwọ yọ jori
Gbọgbọgbọ ni imọ ọ yọ ju ọpẹ
Lo difa fun Afuwape
Ti nfojojumọ nfomi oju sungbere ire
Wọn ni ko bọ ori rẹ
Ki ire gbogbo le sin bọ
Wọn ni Ori laa ba bọ, ka fi Òrìsà silẹ
Afuwape bọ ori
Nijo ba bi ijo, ayọ ba ba ayọ
O ni ibi ti ohun foju si, ona ko gba ibẹ lọ
Ori ẹni ṣe koko
Ori ẹni ṣe pataki
Ori mi gbe mi
Ko o ma ṣe pada lẹhin mi
Bi ori ba gbe ni, a dabi idan
Bi Iṣẹda ba gbe ni
A dabi ogun
Ori lo gbe ọba to fi se ade owo
Ori lo gbe ijoye to fi tẹ ọpa ilẹkẹ
Ori lo gbe bọrọkini to fi wọ agbada ti ntana yinrinyinrin
Ori nii gbe ni taa fi lowo lọwọ
Ori nii gbe ni taa fii bímọ le mọ
Ori nii gbe ṣowoṣowo to ṣowo jere
Ori mi gbe mi
Ma pada lẹhin mi
Ori mi máa ṣe daamu mi
Ori lo daamu Ọlọruntoowo
Ọlọruntoowo kii ṣe ajakaja
Ẹni ti Ori daamu kii ri ere ọja jẹ
Agbẹ to ri idaamu, a rokoroko
Ko ni ere oko mu de'le
Ọde ti ori ba daamu
A dẹ igbo t**i, ko ni ri eran kankan pa
Arinrinajo ti Ori ndaamu, bo ti lọ náà, ni yio bọ lọwọ ofo
Ori mi gbe mi
Maa ṣe jẹ ki nrin Irinajo ofo
Ori nii ko ni yọ lọjọ ibi
Ẹni ori yọ, o di ile
Ori nii gba ni lọwọ ikẹkun awọn pẹyẹpẹyẹ
Afoju fẹni mafọkan fẹni
Ika eniyan ti nfẹjẹ sinu, tutọ funfun sita
Ori mi gbe mi, jẹ kí nraje náà
Tori ba gbe ni, aje a ba ni gbe t**i
Ori mi gbe mi,
Ko ṣa mi si ọdọ awọn olori ire
Translation
I uphold both
I do not single anyone out
If life treats a person well
He is crowned a king
The hands is lifted high above the head.
The palm friends are way higher than the tree
That was the IFA divination cast for Afuwape
Who lamented daily in tears for lack of Ire
He was asked to have Ori bibo
To enable all Ire abide with him
Ori is the major person to venerate, Òrìsà is secondary.
Afuwape had Ori bibọ
All turned to rejoicing and celebration
He said he had put his mind elsewhere but the solution came in differently
Ones Ori is vital
Ones Ori is important
Ori uphold me
Do not forsake me
If Ori upholds a person, it seems like magic
If Ori uphold a person, it seems like charms
Ori uphold a king and gets him crowned richly
Ori uphold chiefs and honours them with the beaded chieftancy walking sticks
Ori upholds important personnels and honours them with flowing shiny robes
It is Ori who uphold and makes us rich
It is Ori who upholds and grants us children
It is Ori who upholds a trader and makes him prosperous
Ori uphold me, do not forsake me
My Ori, do not trouble me
It was Ori who troubled Ọlọruntoowo
Ọlọruntoowo is not a mere person
He who Ori troubles will not make profit in his ventures/business
A farmer troubled by Ori will farm but return home without harvest.
A hunter whom Ori troubles will hunt but find no animal to kill
A traveller whom Ori troubles will go and return empty handed.
Ori uphold me
Do not let me embark on a fruitless journey
It is Ori who delivers us daily from evil
He whom Ori delivers always returns home
It is Ori who saves us from the traps of the predators
They who love us as eye service, but not from within
Wicked ones who deceive us with the intent of their heart
Ori uphold me
Grant me wealth
If Ori uphold a person, Aje will dwell with him for long
Ori uphold me
Count me amongst the prosperous ones.
Lessons
1. Take good care of your Ori
2. Most often we think the problem is external, when indeed it is Ori who is having issues.
3. Ori comes first before any Òrìsà.
4. Ori bibọ is a spiritual rites which align you with Ire, don't neglect it
5. For Ejiogbe in Idafa, Ori bibọ is ideal as part of the prescriptions by IFA.
Please note: Ori bibọ is a core Iṣẹṣe rite, not for churches and mosque. Agbon/Coconut, water and ẹja arọ are not the only ideals for Ori bibọ.
Ori will restore to you all you need and make things right. Take care of your Ori.
All the good things of life, Ire gbogbo, Ori plays a major role in allowing them to manifest.
Declare the iwure above to your Ori.